A ṣe àbẹ̀wò sí arábìnrin Adérónkẹ́ Adéṣọlá Olorì Sports ní ilé iṣẹ́ Splash FM ìlú Ìbàdàn láti sọ nípa iṣẹ́ pàtàkì tí ó ń ṣe nípa ṣíṣe àtúpalẹ̀ eré ìdárayá pẹ̀lú ẹ̀fẹ̀ lórí rédíò lédè Yorùbá.
Olorì Sports ṣàlàyé bí ó ṣe di ògbóǹtarìgì sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ lédè Yorùbá, àwọn tí wọ́n ràn án lọ́wọ́ láti gòkè àgbà, àwọn ìpènijà tí ó kojú àti àwọn àfojúsùn rẹ̀ fún iṣẹ́ tó gbé lọ́wọ́ náà tí í ṣe fífi èdè Yorùbá yangàn ní àwọn ìtàgé tó làmìlaaka káàkiri àgbáńlá ayé.